Bí ìròyìn tó tẹ AWIKONKO lọ́wọ́ laipẹ yìí nípa wí pé Ààrẹ fidihẹ tẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ́ àwọn akọroyin oniṣẹ-iwadii lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìyẹn Nigerian Guild of Investigative Journalists, NGIJ, Ọgbẹni Ọlawale tí wọn lo ń lépa ẹ̀mí akọwe ẹgbẹ́ náà tuntun tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ diboyan, AbdulRahman Aliagan bá fi jẹ òtítọ́, a jẹ pe a fi kí gbogbo ileeṣẹ eleto ààbò má sún asunpara lórí ọ̀rọ̀ yìí, kí wọn sì tọpinpin nnkan tó ń ṣẹlẹ̀ dáadáa.
Ní nǹkan bí ọjọ́ mélòó kan sẹyin ni egbe NGIJ ṣe ìpàdé gbogboogbo wọn lórí ayélujára, níbi tí wọn tí dibo yàn àwọn olóyè ẹgbẹ́ tuntun tí yóò ṣàkóso ẹgbẹ́ náà fún ọdún méjì gbáko.
Kò pẹ lẹ́yìn ìdìbò náà, là gbọ pé Ọlawale Abydeen bẹ̀rẹ̀ si í dunkooko mọ akọwe tuntun yìí, tí wọn sì ni gbogbo ọ̀nà lo ń wá láti lépa ẹ̀mí rẹ.
Nínú lẹta tó fi ranṣẹ sì gbogbo ileeṣẹ eleto ààbò bíi DSS, SSS, to fi mọ ọga ọlọ́pàá pátápátá lórílẹ̀ èdè yìí, Aliagan sọ pé òun kò ní ifọkanbalẹ kankan mọ lásìkò yìí, tó sì ń bẹbẹ pé kí wọn má jẹ ki Abydeen rán òun lọ sọrun àpàpàǹdodo.
Lẹta náà tó pé àkọlé rẹ ni ‘SAVE MY LIFE’ FROM OLAWALE ABIDEEN' ni wọn loo tún fi ranṣẹ sì gbogbo ileeṣẹ ìròyìn pátápátá ní Nàìjíríà láti lè jẹ́ kí wọn mọ pe ọ̀rọ̀ náà kọjá nnkan ti wọn lé máa lérò.
Ọlawale Abydeen jẹ ọkan lára àwọn gbajumọ oniroyin n'ilu Èkó, tó sì tún jẹ́ oludasilẹ ìwé ìròyìn orí ayélujára tó pé ní Security Monitor, gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ.
Nínú lẹ́tà náà ni Aliagan tí sọ pé oṣù kẹfà ọdún yìí ni ẹgbẹ́ NGIJ tí tú igbimọ tó ń ṣàkóso ẹgbẹ́ náà ká, èyí tí Abydeen jẹ́ Ààrẹ fidihẹ fún ọdún mélòó kan sẹyin.
Wọn ní pẹlu awọn iwa aibikita tí Abydeen ń hù, pàápàá bo tun ṣe ń lo orúkọ ẹgbẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí dúkìá ara ẹ láti dunkooko mọ àwọn èèyàn, pàápàá ileeṣẹ, tó fi mọ àwọn banki ni kò tẹ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ lọrun, tí wọn fi gbé igbesẹ láti yan igbimọ ìṣàkóso miran.
Aliagan sọ pé látìgbà tí wọn tí gba ipò náà lọ́wọ́ Abydeen lo tí ń wá gbogbo ọ̀nà láti dojú ẹgbẹ́ náà ru, kò sì gbà ìwé ẹri ẹgbẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó wà láti sọ ọ di ti ara ẹ, èyí tí wọn ní kó ṣeé ṣe fún un.
No comments:
Post a Comment