KWARA WỌGILE ADURA ỌDUN ILEYA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 25, 2020

KWARA WỌGILE ADURA ỌDUN ILEYA

Ki i ṣe ahesọ wi pe kaakiri ipinlẹ to wa ni Naijiria lonii, eyi ti ipinlẹ Kwara naa wa lara wọn ni ajakalẹ arun Koronafairọọsi ti n pọ rẹpẹtẹ lojoojumọ, t'ijọba pẹlu iranlọwọ awọn oṣiṣẹ eleto ilera si n wa ọna abayọ.

Eyi lo mu ki ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq kede wiwọgile adura ọdun Ileya t'awọn Musulumi kaakiri ipinlẹ naa, eyi to maa n waye lọdọọdun.
Ijọba ipinlẹ naa l'oun ko le gba k'awọn eeyan, paapaa awọn ẹlẹsin musulumi korajọpọ lat gbadura fun ayẹyẹ ọdun Ileya, lojuna lati dẹkun itankalẹ ajakalẹ arun Covid-19.

Gẹgẹ bi igbakeji Gomina ipinlẹ naa, Ọgbẹni Kayọde Alabi ṣe ṣalaye f'awọn oniroyin l'ọjọ Fraide ana, o n'ijọba ko le laju silẹ ki arun naa pọ si pẹlu obitibiti owo ti wọn n na lati ri i pe arun naa tan nilẹ.

Bẹẹ nijọba tun fófin de iṣọ-oru f'awọn ṣọọṣi, mọṣalaṣi, ati ode ariya, ile igbafẹ, to fi mọ otẹẹli at'awọn ile iworan bọọlu.
Alabi jẹ ko di mimọ pe ijọba ti gbe awọn igbimọ kan dide lati ri i pe awọn eeyan ko kọti ikun si ofin ati ilana ijọba lori kikorajọpọ.

Yatọ si eyi, ijọba Kwara tun kede sita pe awọn ile ounjẹ, ile igbafẹ igbalode ati ile itaja igbalode bi i shoprite, Amusement Park to fi mọ ọja, ni wọn ko ni i ṣilẹkun lọjọ ọdun Ileya.

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni: Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Kayọde Ẹgbẹtokun; ọga Sifu Difẹnsi, Bello Ale; awọn aṣoju ẹsin Council of Ulamah, Imaamu Imale tilu Ilọrin Sheikh Abdullah AbdulHameed ati Onidajọ Salihu Muhammed at'awọn mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI