Lati le je k'awon araalu wa ni ilera pipe, ijoba ipinle Kwara labe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gbe owo sile lati fi pin aawon-apefon (Mosquito Nets), eyi to n gbogun ti itankale aisan iba laarin ilu.
Lonii ni Komisanna fun eto ilera, Dokita Raji Razaq gbe eto naa de odo awon lobaloba n'ilu Ilorin, eyi ti won fi n palemo mo ti ipolongo aawon-apefon t'odun 2020 n'ipinle naa.
N'igba to n gba enu Komisanna soro, alakoso eto naa, Alaaji Abdullahi Nageri so nipa bi Gomina AbdulRazaq se n sa ipa re lati dekun aisan iba laarin ilu, paapaa kaakiri ipinle naa.
O wa ro awon igbimba naa lati tubo parowa s'awon araalu lati jade gba aawo-apefon naa, ki won si lo o lona to ba ye, ki alaafia ati ilera pipe le tubo joba.
Balogun Gambari ilu Ilorin, Alaaji Adebayo Mohammed dupe lowo Gomina AbdulRazaq fun ise takuntakun to n se, paapaa leka eto idagbasoke ipinle naa, eyi ti ko sele ri.
No comments:
Post a Comment