KORONAFAIRỌỌSI! ÀÁDỌ́TA ÈÈYÀN KAGBAKO N'ILE IGBAFẸ NI KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 18, 2020

KORONAFAIRỌỌSI! ÀÁDỌ́TA ÈÈYÀN KAGBAKO N'ILE IGBAFẸ NI KWARA


Àwọn tí kò dín ni àádọ́ta ni wọn ti k'àgbákò n'ilu Ilọrin laarọ òní ọjọ́ Satide, Abamẹta nílé igbafẹ kan, níbi tí wọn làwọn èèyàn náà tí lọọ jaye orí wọn. 

Òfin konilegbele àti òfin tó dé ipejọpọ èèyàn rẹpẹtẹ lẹẹkan ṣoṣo là gbọ pé àwọn èèyàn náà tàpá sí í, èyí tó mú k'awọn igbimọ tó ń rí sọ̀rọ̀ àrùn COVID-19 nipinlẹ Kwara lọọ rọwọ tó wọn. 

Alaga igbimọ idanilẹkọọ lórí àrùn koronafairọọsi nipinlẹ náà, Dọkita Fẹmi Ọladiji lo fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ nílé tí wọn yà s'ọtọ láti máa tọ́jú àwọn tó lugbadi arun náà, ìyẹn isolation Centre tí wọ́n tọju àwọn èèyàn náà sí í. 

Ọladiji lo jẹ́ kó ye wá pé igbá-kejì Gómìnà ipinlẹ náà, Ọgbẹni Kayọde Alabi, ẹni tó tún jẹ́ alaga ìgbìmọ̀ olùṣàkóso ajakalẹ àrùn náà lo lewaju bí wọn ṣe rí àwọn èèyàn náà mú. 

Oníṣègùn òyìnbó, Ọladiji sọ pé àwọn tí ọjọ́ wọn kò ju ogún ọdún sì ọgbọn ọdún lọ làwọn t'ọwọ tẹ náà ni otẹẹli Kwara ni nnkan bí aago kan òru. 

 Ṣáájú àsìkò yìí ni ìjọba àpapọ̀, tó fi mọ àwọn ìjọba ipinlẹ tí sọ pé kí gbogbo otẹẹli àti ilé igbafẹ, gbogbo ilé ìjọsìn wa ni títí pá, nítorí tí wọn kò fẹ́ kí ipejọpọ tó lè ní mẹ́wàá ṣẹlẹ̀ láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ ajakalẹ àrùn COVID-19. 

Ọladiji fi ye wá pé àwọn tí gba ayẹwo lára àwọn èèyàn náà, tó sì ni kò di wọn lọ́wọ́ láti fi wọn jofin. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI