KỌMIṢANNA ṢABẸWO S'AWỌN ÀKÀNṢE IṢẸ́ TO Ń LỌ LỌ́WỌ́ NI KWARA, BẸ́Ẹ̀ LO GBÉ OṢUBA KARE FÚN GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 2, 2020

KỌMIṢANNA ṢABẸWO S'AWỌN ÀKÀNṢE IṢẸ́ TO Ń LỌ LỌ́WỌ́ NI KWARA, BẸ́Ẹ̀ LO GBÉ OṢUBA KARE FÚN GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ


Lọ́jọ́ Wẹside àná ni kọmiṣanna fún ọ̀rọ̀ eto àyíká àti agbegbe, Arc Aliyu Muhammad Saifuddeen ṣabẹwo sáwọn àkànṣe iṣẹ́ afara àti kọta ti ìjọba gbé fáwọn agbaṣẹṣe. 

Nibẹ lo sì ti gbé oṣuba rabandẹ fún Gómìnà AbdulRazaq lórí bí kò ṣe fi nnkan falẹ nipinlẹ náà. 

Ọkàn lára àwọn àkànṣe iṣẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́ ni ti Odo Asa tó wà lágbègbè Unity, èyí tí wọn tí gbé fáwọn agbaṣẹṣe láti ṣe àtúnṣe lee lórí, fún ìgbádùn àwọn aráàlú.





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI