IṢẸ́ ÀGBẸ̀! ÌJỌBA KWARA FẸẸ DA ÀWỌN Ọ̀DỌ́ L'Ọ́LÁ L'ÁRÀ Ọ̀TỌ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 1, 2020

IṢẸ́ ÀGBẸ̀! ÌJỌBA KWARA FẸẸ DA ÀWỌN Ọ̀DỌ́ L'Ọ́LÁ L'ÁRÀ Ọ̀TỌ̀


Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara tí sọ pé òun yóò pèsè ààyè rẹpẹtẹ silẹ f'áwọn ọdọ ipinlẹ náà láti fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ àgbẹ̀ àti ọgbin, ní ìbámu pẹ̀lú ètò àgbẹ̀ lábẹ́ ìjọba àpapọ̀, èyí tí wọn pé ní Federal Government’s National Agricultural Land Development Authority (NALDA) initiative.

AbdulRazaq ni òun yóò yà àwọn ilẹ̀ tí kò dín ni ẹẹdẹgbẹta ẹkita {500 hectares} sọtọ, tí wọn yóò sì pín in fún àwọn ọdọ tí wọn ba nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ àgbẹ̀ àti ọgbin. 

Ó sọrọ náà n'ilu Abuja lásìkò tó ń báwọn akọroyin sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé tó ṣe pẹ̀lú aláṣẹ ileeṣẹ NALDA, Ọmọba Paul Ikonne. 

Gómìnà sọ pé ilẹ̀ ẹẹdẹgbẹta ẹkita náà yóò jẹ́ ifaara làwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta, bí tilẹ̀ jẹ́ pé káàkiri ipinlẹ náà ni yóò ti padà ṣe é. 

Ó ní erongba ìjọba ni lati jẹ́ káwọn ọdọ, ìyẹn àwọn tó ti jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga àtàwọn tí wọn kò tíì bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ gíga mọ pe iṣẹ gidi ni iṣẹ́ àgbẹ̀ jẹ́. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI