Lọ́jọ́ Wẹside òní ni ìjọba ipinlẹ Kwara bá àwọn olórí ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí tí wọn pé Council of Ulamah nipinlẹ náà, èyí tí Emir tilu Ilọrin, Dókítà Ibrahim Sulu-Gambari jẹ́ olórí wọn ṣe ìpàdé lórí ọ̀nà tí wọn yóò gbé eto àdúrà ọdún Ileya kalẹ.
Ọ̀nà láti dẹ́kun itankalẹ àrùn COVID-19 tí a tún mọ sì koronafairọọsi nijọba ń wá, ní ìbámu pẹ̀lú òfin tó dé ipejọpọ eleeyan rẹpẹtẹ.
Lára àwọn tó wà níbi ìpàdé náà láti mọ ọ̀nà tí wọn yoo gbe àdúrà Eid-ul-Adha gba náà ni: Imaamu Imale tilu Ilọrin, Sheikh Abdullah AbdulHameed to lewaju won; Imaamu Àgbà tilu Ọfa, Sheikh Muhyideen Husayn; Adajọ-fẹhinti Salihu Mohammed; Onidajọ Abdul Mutallib Ahmad Ambali; Ọjọgbọn Badmas Yusuf; Onidajọ Idris Abdullahi Haroon; àti Ọmọwe Abdulrazaq Amuda.
Nibẹ làwọn aṣojú ìjọba tó wà nibẹ tí dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olórí ẹlẹ́sìn náà fún ifọwọsowọpọ wọn, àti ìdúróṣinṣin wọn fún ìjọba, bẹ́ẹ̀ ni wọn ní kí wọn lọ fọkàn balẹ̀ nítorí pé dídùn ni eso yóò so bí yóò bá fi di Ọjọ́ Ẹti.
Àwọn aṣojú ìjọba tó wà níbi ìpàdé náà ni ó igbakeji Gómìnà, Ọgbẹni Kayọde Alabi; Kọmiṣanna fún eto ìlera, Dọkita Raji Razaq; Kọmiṣanna fún eto ìròyìn, Adenikẹ Afolabi-Oshatimẹhin; Oludamọran pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú, Saadu Salahu; Amugbalẹgbẹ pàtàkì fún gomina lórí ọ̀rọ̀ ẹsin Isilaamu, Danmaigoro Ibrahim; Alákóso eto ìlera, Dọkita Oluwatosin Fakayọde.
Àwọn yòókù ni: Ọmọwe Ghali Mohammed; Ọjọgbọn àti Alákóso lẹka National Orientation Agency, Oluṣẹgun Adeyẹmi.
No comments:
Post a Comment