ILEEṢẸ TẸLIFIṢAN NTA JÓNÀ N'ILỌRIN, GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ ṢE BẸBẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 22, 2020

ILEEṢẸ TẸLIFIṢAN NTA JÓNÀ N'ILỌRIN, GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ ṢE BẸBẸ


Lalẹ àná, Tuside ni nnkan bí aago mọkanla kọjá ìṣẹ́jú mẹẹdọgbọn ni ariwo ńlá sọ nileeṣẹ tẹlifiṣan NTA tilu Ilọrin, nígbà tí iná dee de ṣẹyọ. 

Kò dín ni ọfiisi mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó fi mọ gbọngan ìpàdé kan ló jóná gburugburu níbi ìjàmbá iná náà, tí agbẹnusọ ileeṣẹ panapana nipinlẹ náà, Hassan Adekunle sì fìdí rẹ múlẹ̀. 

Kopẹ tí wọn ní iná náà dee de ṣẹyọ tí wọn fi ranṣẹ sáwọn panapana, táwọn náà kò sì pe ki wọn tó o debẹ. Ìṣẹ́jú mẹ́rin tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ là gbọ pé àwọn òṣìṣẹ́ panapana tí debẹ, tí wọn sì gbìyànjú láti dawọ iná náà dúró. 

Lójú ẹsẹ̀ tí ròyìn náà tí tẹ Gomina AbdulRazaq létí lòun náà tí gbéra lọ síbẹ̀ láti wo nnkan tó ń ṣẹlẹ̀, tó sì báwọn kẹdun lórí bí wọn ṣe pàdánù àwọn dúkìá olówó iyebíye. 


Aago kan òru Ọjọru, Wẹside òní là gbọ pé Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tí debẹ pẹ̀lú àwọn ikọ akọwọrin ẹ mélòó kan láti wá ọ̀nà àbáyọ fún wọn. 

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Gómìnà AbdulRazaq sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé nnkan ti ko dùn mọ ẹnikẹ́ni nínú ni, síbẹ̀ ìdùnnú àti ayọ̀ lo jẹ́ pé kò mú ẹmi lọ, tó sì tó ọpẹ. 

Gẹ́gẹ́ bí atẹjade tí Rafiu Ajakaye tó jẹ́ akọwe Gómìnà fi síta nípa ọ̀rọ̀ Gómìnà lo tí sọ pé báwọn iléẹṣẹ́ panapana ṣe tètè debẹ lo jẹ́ kí àjálù naa tètè dawọ dúró. 


Bẹ́ẹ̀ lo gbé orí yín fún iléẹṣẹ́ NTA lórí igbesẹ wọn láti tètè pariwo síta, àti bí wọn ṣe fi tó àwọn iléẹṣẹ́ panapana létí, èyí tí kò jẹ kò ṣe ìjàmbá pupọ fún wọn. 

Bákan náà lo gba wọn lamọran láti máa wà ní òfin tótó nípa iná, kí wọn sì rí í dájú pé wọn ń pá àwọn iná tó bá yẹ kí wọn pá lásìkò, pàápàá nígbà tí wọn kò bá sì ní ọ́fíìsì. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI