ÌDÍLÉ ARULOGUN GBÀRÀ DÁ N'IPINLẸ Ọ̀YỌ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 30, 2020

ÌDÍLÉ ARULOGUN GBÀRÀ DÁ N'IPINLẸ Ọ̀YỌ́


Titi di àsìkò tá a kọ ìròyìn yìí tán làwọn èèyàn ṣí ń sọ̀rọ̀ lórí ara ti ìdílé ńlá kan n'ipinlẹ Ọ̀yọ́, ìdílé Arulogun gbà dá laipẹ yìí, lórí bi wọn ṣe ṣe iranlọwọ fáwọn iléèwé kọọkan nipinlẹ náà. 

Àwọn nǹkan iranwọ tó lè dènà itankalẹ àrùn koronafairọọsi ni ìdílé Arulogun fún àwọn iléèwé n'ilu Arulogun, ìpínlẹ̀ náà báwọn iléèwé alakọbẹrẹ àti gírámà ṣe ń palẹmọ láti wọlé. 


Lára àwọn nǹkan yi wọn fún wọn ní aṣọ ibomu-boju, ike omi, ifọwọ {hand sanitizers} at'awọn mi in. 

Èyí ni wọn ṣe láti fi rán ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́wọ́ láti rí í pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò lugbadi àrùn Covid-19 


Ìdílé Arulogun tí àwọn olórí ẹbí bíi Mọgaji Arulogun àti Jagun-Balogun ìlú Ìbàdàn, Oloye Mọnsur Arulogun lewaju wọn sọ pé ìjọba kò lè dá eto naa ṣe tán, ìdí rèé tó làwọn fi dìde láti rán ìjọba lọ́wọ́. 

Bẹ́ẹ̀ lo gbawọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ lamọran lórí ọ̀nà tí wọn lé gba láti máa lo àwọn nǹkan náà. 


Lára àwọn tí wọn tún wà níbi eto naa ni Olóyè Timothy Oluyọmbọ Arulogun, Baalẹ tuntun tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn,  Olóyè Lawal Taofeq Arulogun àtàwọn min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI