IDAAMU NLA DE B'AWỌN ỌMỌ IPINLẸ OGUN LORI ILE WỌN T'IJỌBA IPINLẸ EKO FẸẸ WO DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 27, 2020

IDAAMU NLA DE B'AWỌN ỌMỌ IPINLẸ OGUN LORI ILE WỌN T'IJỌBA IPINLẸ EKO FẸẸ WO DANU

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, inu ibanujẹ ọkan lawọn olugbe Agbado-Okearo to wa níjọba ibilẹ Ifọ, ipinlẹ Ogun wa bayii lori b'ijọba ipinlẹ Eko ṣe sọ pe awọn ṣetan lati wo ile ti ko din ni irinwo to wa nibẹ lulẹ.

Gbogbo awọn onile ati ayalegbe ni wọn n rawọ ẹbẹ sijọba Dapọ Abiọdun lati tete wa nnkan ṣe si i nitori pe ibi tijọba Eko fẹẹ wo ki i ṣe ara ipinlẹ Eko, bi ko ṣe pe ipinlẹ ogun ni.

Ileeṣẹ to n ri si ọrọ omi nípinlẹ Eko, iyẹn Lagos State Water Corporation ni wọn f'awọn ara agbegbe naa niwe lati kuro nibẹ, nitori pe awọn fẹẹ lo awọn agbegbe naa, ti wọn si ti fi ontẹ si ara ile ti ko din ni irinwo ti wọn fẹẹ wo danu.

Ninu lẹta ti alaga idagbasoke agbegbe Agbado-Okearo, Ọgbẹni Samso Abegunde kọ ranṣe si Gomina Dapọ Abiọdun lọjọ Aiku, Sannde ana lo ti rawọ ẹbẹ wi pe ko sọ fun Gomina Babajide Sanwo-Olu lati dawo duro lagbegbe naa, ati pe ile ti wọn fẹẹ wo ko si lara ipinlẹ Eko, bi ko ṣe ipinlẹ Ogun.

Awọn ile ti wọn fi aami si lati wo la gbọ pe ileeṣẹ to n ri sọrọ omi n'ipinlẹ Eko naa fẹẹ gbe ọpa omi ti yoo kọja lọ si Eko gba.

Abegunde sọ pe lati nnkan bi ọdun 1972 l'awọn eeyan ti n gbe lagbegbe yii lai si wahala tabi idaamu kankan, to si ni lẹyin ogun abẹle l'awọn ti n gbebẹ, ko to o di pe ileeṣẹ omi debẹ l'ọdun 1986.

Ọkunrin naa sọ pe pupọ awọn onile to wa nibẹ lo ni ojulowo iwe ilẹ ati ile wọn lọwọ, nitori pe ijọba ipinlẹ Ogun lo fun wọn l'aṣẹ lati kọ ile sibẹ.

O tun fi kun ọrọ rẹ pe pupọ awọn onile ni wọn dagbere faye nigba ti ileeṣẹ omi yii ṣiṣẹ gbẹyin lagbegbe naa, nigba ti wọn ko ri ẹtọ wọn gba lọwọ wọn.

Ninu ọrọ tiẹ, Kọmiṣana feto iroyin n'ipinlẹ Eko, Gbenga Ọmọtọṣhọ sọ pe ijọba ipinlẹ Eko ati Ogun ni wọn jọ fọwọsowọpọ lati ṣe ọpa omi naa, ti ki i si i ṣe ipinu ijọba Eko nikan.

Kọmiṣanna sọ pe ijọba Eko ti ṣetan lati fun awọn tọrọ kan lowo gba ma binu, ti ko si sijọba to fẹẹ fi tipatipa lẹ ẹnikẹni danu lai wa ọna abayọ fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI