GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ ṢÈLÉRÍ OWO IRANWỌ FÁWỌN ILÉ-Ẹ̀KỌ́ ÀDÁNI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 18, 2020

GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ ṢÈLÉRÍ OWO IRANWỌ FÁWỌN ILÉ-Ẹ̀KỌ́ ÀDÁNI


Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara tí sọ pé òun yóò ṣe iranlọwọ owó fún gbogbo àwọn iléèwé aladani káàkiri ipinlẹ náà láti lè jẹ ki eto ẹ̀kọ́ We’ll kẹsẹjari, pàápàá lásìkò tí ajakalẹ àrùn COVID-19 dojú nnkan ru.

Ọjọ́ Ẹti, Fraide àná ni Gómìnà AbdulRazaq ṣe ìlérí yìí wí pé eto ẹ̀kọ́ orí ayélujára tí de, ó sì ti dúró, àti pé ó di dandan kó fi ẹsẹ múlẹ̀.
 
Gómìnà AbdulRazaq ni eto ẹyawo ti wá nílẹ̀ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti oludasilẹ ilé ẹ̀kọ́ aladani láti fi rán wọn lọ́wọ́ lásìkò konilegbele yìí, kí eyo ẹ̀kọ́ má bá a dúró. 

Ó ní ọ̀nà láti lè san owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ wọn lo mú kí ìjọba ronú ọ̀nà láti rán wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú ẹyọ ẹyawo náà tí wọn pé ní interest-free loan and grants. 

Eto ẹyawo náà là gbọ pé kò ní èlé {interest} nínú rárá, tó sì ti ń mú káwọn èèyàn máa dunnu pé ìgbà ọtun tí de. 
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI