GBAJUMỌ PASITỌ KU LOJIJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 4, 2020

GBAJUMỌ PASITỌ KU LOJIJI

Gbajugbaja oludasilẹ ṣọọṣi kan ti wọn pe ni Father’s House Bible Church to wa ni Effurun, ipinlẹ Delta, Pasitọ Richmond Leigh ni wọn ti kede iku rẹ lojiji.

Ọjọ Ẹti, Fraide ana ni wọn ni gbajumọ Pasitọ naa dagbare f'aye ni ọsibitu kan to wa nilu Warri lẹyin aisan rampẹ.

Pasitọ naa ti wọn sọ pe oun lo kọkọ bẹrẹ ipade ọlọdọọdun keresimesi t'awọn ọmọ ijọ mi in yoo kopa n'ilu warri ati Effurun, ipinlẹ Delta la gbọ pe o ti ja aja yege lori ọrọ ilẹ eeka meje pẹlu ilu Ubeji, n'igba ti ile-ẹjọ agba lorilẹ-ede yii daa lare.

 
AWIKONKO gbọ pe bi Pasitọ t'awọn eeyan tun pe ṣọọṣi ẹ ni Richmond Susan Leigh Ministries ni ẹka si ipinlẹ Rivers ati Eko.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI