Iroyin to ba ni lọkan jẹ gidi ni b'awọn ti ko din ni mẹrin ṣe ku sinu ijamba ori omi l'Ekoo l'ọjọ Ẹti ti i ṣe Fraide ana.
Agbegbe Ebute Metta-Ero nitori Lagos Island la gbọ pe ọkọ oju omi naa ti gbera, to si n lọ si abegbe Agbegbe Ikorodu, ko to di pe iṣẹlẹ ijamba naa waye lagbegbe Agbọwa.
Titi di asiko ta a fi kọ iroyin yii tan la gbọ pe wọn ko ti i ri balogun ọkọ naa ati ọmọṣẹ rẹ, ṣugbọn t'awọn ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri n'ipinlẹ Eko, iyẹn LASEMA ṣi n wa wọn.
Oku awọn mẹfa la gbọ pe wọn ti ṣawari bayii, ti won si ti ko wọn lọ si mọṣuari ọsibitu jẹnẹra to wa ni Ikorodu.
No comments:
Post a Comment