EYI NI BI AYỌ MOJOYIN ṢE DI AARẸ ẸGBẸ AKỌROYIN ONIṢẸ-IWADII {NGIJ} LORILẸ-EDE NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 28, 2020

EYI NI BI AYỌ MOJOYIN ṢE DI AARẸ ẸGBẸ AKỌROYIN ONIṢẸ-IWADII {NGIJ} LORILẸ-EDE NAIJIRIA

Kaakiri agbaye ni l'awọn ololufẹ gbajumọ akọroyin lorilẹ-ede Naijiria, Ayọyẹmi Mojoyinọla ti n fi lẹta ikinni ranṣẹ sii lori bo ṣe di Aarẹ ẹgbẹ awọn akọroyin oniṣẹ-iwadii, iyẹn Nigeria Guild of Investigative Journalists, NGIJ.

Ọjọ Mọnde ana l'awọn ọmọ ẹgbẹ naa dibo yan Mojoyinọla gẹgẹ bi Aarẹ ẹgbẹ wọn ti yoo ṣakoso ẹgbẹ fun ọdun meji gbako.

Ayọyẹmi Mojoyinọla ni oludasilẹ iwe iroyin kan to gbajumọ daadaa lorilẹ-ede Naijiria, paapaa l'awọn orilẹ-ede kan lagbaaye, iyẹn iwe iroyin THE CITY PULSE {thecitypulsenews.com).

Yatọ si Mojoyin to jẹ Aarẹ egbẹ naa, awọn mi in ti wọn tun dibo yan ni Baṣọrun Israel Bọlaji to jẹ igbakeji Aarẹ lori ọrọ iroyin {Vice President, Information & Strategy}; Kọmureedi James Ezema toun naa jẹ igbakeji Aarẹ lori ọrọ iṣẹ iwadii {Vice President, Investigations}; ati AbdulRahman Aliagan toun jẹ akọwe ẹgbẹ naa.

Awọn mi in ti wọn tun dibo yan ni Oyewale Oyelọla toun jẹ olugbaniwọle {Registrar}; Rowland 'Shuwa toun jẹ akọwe iṣuna {Financial Secretary} ati Fẹmi Oyewale toun naa jẹ alukoro ẹgbẹ {Public Relations/Welfare Officer}.

Ori ikanni ayelujara ni eto idibo naa ti waye nibi ipade gbogboogbo wọn to waye, eyi ti wọn ṣe nibamu pẹlu ofin ati ilana lati dẹkun ajakalẹ aarun Covid-19, eyi ti ko faaye gba ipejọpọ elero pupọ.

Alaga eto iṣakoso idibo, Ọgbẹni Temitọpẹ Sunday nígba to n gbe iroyin ibo naa sita sọ pe iṣakoso Mojoyinọla pẹlu awọn ti wọn jọ dibo yan yoo gbe eto idibo abẹle kalẹ yan awọn mi in s'awọn ipo to ṣofo.

Sunday ni eto idibo akọkọ ree ti yoo waye ninu ẹgbẹ naa, to si tun ni eto idibo naa waye lai ni ikunsinu tabi wahala kankan ninu, bẹẹ lo fi kun un pe apẹẹrẹ rere ni ẹgbẹ naa tun fi lelẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ tuntun naa, Ayọyẹmi Mojoyinọla sọ pe oun dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa fun aduroti wọn, to si ṣeleri pe ibi giga loun yoo mu ẹgbẹ naa lọ, ati pe iṣakoso oun ko ni i fi ti ẹlẹyamẹya ṣe.

O wa a gba awọn ọmọ ẹgbẹ naa lamọran lati fọwọsowọpọ pẹlu iṣakoso oun, to si gbadura pe Ọlọrun yoo tubọ mu ẹgbẹ naa gun oke agba bi t'awọn ti iṣaaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI