Ile-ẹjọ giga kan to jokoo silu Benin, ipinlẹ Ẹdo ti sọ ọkan lara awọn gbajumọ ọmọ Yahoo ti wọn pe orukọ ẹ ni Samson Osawaru sẹwọn ọdun meji gbako pẹlu iṣẹ aṣekara.
Onidajọ Demi-Ajayi to da ẹjọ naa laipẹ yii tun fi aaye silẹ lati san owo itanran miliọnu kan naira, iyẹn bi Samson ko ba fẹẹ lọ si ẹwọn.
Ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹ-ede Naijiria lo fóju Samson ba ile-ẹjọ lori ẹsun jibiti ori ayelujara.
No comments:
Post a Comment