Ẹ DARI JI MI, MO TI ṢE AṢIṢẸ NLA L'ẸDO - ỌṢIỌMỌLẸ BU SẸKUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 27, 2020

Ẹ DARI JI MI, MO TI ṢE AṢIṢẸ NLA L'ẸDO - ỌṢIỌMỌLẸ BU SẸKUN

Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti wọn yọ danu, Kọmureedi Adams Ọṣiọmọlẹ ti sọ pe ka ni oun mọ pe ọja ti ko dara rara ni Gomina ipinlẹ Ẹdo t'oun ṣagbatẹru wiwọle ẹ l'\dun 2016, oun ki ba ti wa ẹlomi in gbe dide.

Ọṣiọmọlẹ sọ pe idi pataki toun ṣe fa ọwọ Gomina Godwin Ọbasẹki s'oke l'ọdun 2016 ni lati tẹsiwaju awọn akanṣe iṣẹ ati eto toun ṣe ku, lai mọ pe ko ni i dawọle wọn.
 
Ọjọ Aiku, Sannde ana ni Ọṣiọmọlẹ sọrọ yii lasiko to n b'awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ṣe ipade ni Government Reservation Area to wa n'ilu Benin, ipinlẹ Ẹdo.

Nibẹ lo ti iwe adehun lasan ni Ọbasẹki jẹ, ati pe eeyan Ọlọrun gidi ni Pasitọ Ọsagie Ize-Iyamu jẹ, ẹni ti yoo si ri i daju pe ijọba gidi n tẹsiwaju lọjọ kejila oṣu kọkanla ọdun yii.

"Mo ti ṣe aṣiṣe nla. Ọlọrun nikan lo pe. Ọmọ ọdun mejidinlaadọrin (78) ni mi bayii. Mo si ti wa a bẹbẹ fun aṣiṣe ti mo ṣe lati ṣagbatẹru Ọbasẹki l'ọdun 2016. Mo ti pada s'ipinlẹ Ẹdo bayii lati tun aṣiṣẹ naa ṣe.

"Ọbasẹki ti ṣi ipo naa lo, to si ti dalẹ awọn ara Ẹdo. Pẹlu kaadi idibo alalopẹ wa, a maa fiya jẹ Ọbasẹki lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹsan-an to n bọ. Ize-Iyamu ko ni i tun aṣiṣe Ọbasẹki ṣe, yoo si mu ipinlẹ Ẹdo lọ si ipele giga."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI