ÀWỌN ÈÈYÀN TÚN SỌ̀RỌ̀ BURÚKÚ SÌ ÌYÀWÓ AJIMỌBI, L'ORI IKÚ ỌKỌ RẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 1, 2020

ÀWỌN ÈÈYÀN TÚN SỌ̀RỌ̀ BURÚKÚ SÌ ÌYÀWÓ AJIMỌBI, L'ORI IKÚ ỌKỌ RẸ


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, àsìkò yìí kò tún fẹẹ dùn fún ìyàwó Gómìnà àná nipinlẹ Ọ̀yọ́, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi, Arábìnrin Florence Ajimọbi lórí bí wọn ṣe sọ pé kò gbajumọ àwọn nǹkan tó yẹ kó gbajumọ, tó jẹ́ pé ìjọba Ọ̀yọ́ lo ń fojoojumò takò lọ. 

Ohun tá a gbọ ni pé látìgbà tí ọkọ rẹ, Abiọla Ajimọbi tí kú, ní wón sọ pé ìyàwó rẹ kò ti tí ṣọọbu ẹ ti wọn pé ní GRANDEX STORE to wá n'ilu Ìbàdàn pá. 

A gbọ pé obìnrin náà kò pàṣẹ fáwọn ọmọṣẹ rẹ àtàwọn alakoso ṣọọbu náà láti tí í pá fúngbà díẹ̀, pẹ̀lú erongba láti fi kẹdun ikú olóògbé náà. 


Laipẹ yìí ni obìnrin náà sọ̀rọ̀ burúkú sì Gómìnà Ṣeyi Makinde wí pé kò pé òun lórí ikú ọkọ òun, bẹẹ si ni kò jẹ káwọn sìn ọkọ rẹ síbi tí wọn fẹ. 

Bí àwo èèyàn ṣe rí ohun tí Florence ṣe yìí, lo mú kí wọn máa sọ̀rọ̀ burúkú sii pé òun fúnra rẹ kò nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ dénú, àti pé ojú ayé lásán lo ń ṣe.

Wọn ní ká ní o nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ ni, ó yẹ kó yà ọjọ kan ṣoṣo sọtọ láti tú ṣọọbu rẹ pá, ìyẹn bí ikú ọkọ rẹ bá dùn ún. 

Bẹẹ ni wọn tún ní kó gbé ẹnu rẹ dakẹ láti máa sọ̀rọ̀ sì Gómìnà Makinde nítorí pé kò sí nnkan tó kàn Makinde nínú ọ̀rọ̀ ikú ọkọ rẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI