Láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àìsàn ibà {Malaria}, kò dín ni mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ {2.3m} àwọ̀n apẹfọn ni wọn ti ko de ipinlẹ Kwara bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, èyí tí wọn fẹẹ pín fáwọn aráàlú.
Èyí ni lára àwọn ìlérí tí Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq ṣe lásìkò ìpolongo ìdìbò lọdun tó kọjá wí pé òun yóò rí i dájú pé àwọn aráàlú wá nù ìlera pípé àti àlàáfíà.
Àwọn òṣìṣẹ́ tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún márùn-ún là gbọ pé ìjọba fẹẹ gba láti pín àwọ̀n apẹ̀fọn náà fáwọn aráàlú.
Ilé tí kò dín ni 772,648 là gbọ wọn yóò jẹ àǹfààní àwọn apẹ̀fọn náà.
No comments:
Post a Comment