AKEREDOLU F'OJU AWỌN OLUDIJE MẸWAA GBOLẸ NIBI IDIBO ABẸLE ẸGBẸ OṢELU APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 21, 2020

AKEREDOLU F'OJU AWỌN OLUDIJE MẸWAA GBOLẸ NIBI IDIBO ABẸLE ẸGBẸ OṢELU APC


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, inú ìdùnnú àti ayọ̀ ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Òndó, Arákùnrin Rotimi Akeredolu àtàwọn olólùfẹ́ rẹ wà báyìí, lórí bó ṣe wọlé gẹ́gẹ́ bí oludije sípò gomina lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC. 

Ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá ni eto idibo sípò Gómìnà yóò wáyé nipinlẹ Òndó, níbi táwọn aráàlú yóò ti yàn ẹni tí wọn tún fẹ́ kó ṣe olórí wọn fún ọdún mẹ́rin gbáko. 


Nnkan bí aago méjìlá kọjá ìṣẹ́jú mẹẹdọgbọn òru òní ni wọn kéde esi ibo náà pé Gómìnà Akeredolu tí borí àwọn oludije méje tí wọn dupo abẹle náà. 

Ibo 2,458 là gbọ pé Akeredolu fi borí ẹni tó ṣe ipò kejì, ìyẹn Oluṣọla Ọkẹ tòun ni ibo 262 káàkiri gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ tó wà nipinlẹ náà. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI