WAHALA ATI IBẸRUBOJO NLA DE B'AWỌN AFIPA-BANI-LAṢEPỌ NI KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 18, 2020

WAHALA ATI IBẸRUBOJO NLA DE B'AWỌN AFIPA-BANI-LAṢEPỌ NI KWARA


Pẹlu ọrọ nla to jade sita l'Ọjọru tii ṣe Wẹside ana n'ipinlẹ Kwara bayii n'ipa awọn to n fipa b'awọn obinrin laṣepọ kaakiri, awọn oniṣẹ ibi naa la gbọ pe wọn ti n palẹmọ ẹru wọn lati sa kuro nilu.

Lẹnu ọjọ mẹta yii, awọn iṣẹlẹ ifipabanilaṣepọ lo n gba igboro kan, ti awọn ti ko din ni mẹrin si ti jade laye nipa iṣẹlẹ naa laarin oṣu kan.

Ni bayii, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ki gbogbo awọn to hu iru iwa naa tete lọọ t'ọwọ wọn bọ aṣọ, tabi pe ki wọn fi ilu naa silẹ, iyẹn bi wọn ko ba fẹẹ fi oju winna ofin ipinlẹ naa.

Ijọba Kwara l'ohun ko le la oju oun silẹ ki iru awọn iwa ibajẹ bẹẹ maa tẹsiwaju labẹ iṣakoso oun, iyẹn iṣakoso OTOGẸ.

Kii ṣe ahesọ mọ pe ijọba yii ti mu awọn ayipada rere de ba ipinlẹ naa laaarin ọdun kan to gba ijọba, lara wọn si ni ti idagbasoke l'ẹka eto-ẹkọ, ilera, opopona, agbegbe to m'aye-dẹrun ati bẹẹ bẹe lọ. 

N'igba to n sọrọ n'ilu Ilọrin, Kọmiṣanna f'ọrọ iroyin ati ikansira-ẹni n'ipinlẹ naa, Alaaji Muritala Ọlanrewaju sọ pe awọn ti gbe pẹrẹki kana f'awọn oniṣẹ ibi naa, ti ilu ko si ni jọọ gba awọn mejeeji.

O sọrọ yii lasiko to n gba igbimọ ajafẹtọ-ọmọniyan, ẹka t'ipinlẹ naa lalejọ ni ọfiisi rẹ

Alaaji Ọlanrewaju sọ pe iṣẹlẹ ifipabanilopọ yii n pọ si lawujọ Naijiria lojoojumọ, to si l'awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati f'iya jẹ awọn eeyan naa ti ọwọ ba tẹ labẹ ofin.

Bẹẹ lo l'awọn yoo bẹrẹ ikede lati dẹkun iwa naa lori redio, tẹlifiṣan ori ayelujara ati laaarin ilu laipẹ, o n wa bẹ awọn ajafẹtọ-ọmọniyan naa lati gbaruku ti ijọba lojuna lati dẹkun iwa yii.

Ṣaaju asiko yii, Adari ileeṣẹ ajafẹtọ-ọmọniyan n'ipinlẹ Kwara, Arabinrin Jumọkẹ Ọlaoye kanminu pupọ lori iwa ifipabanilopọ, to si l'awọn oniṣẹ ibi yii n fi oju awọn obinrin han mabo, eyi to lo n jẹ kayeefi.

Bẹẹ lo rawọ ẹbẹ s'ijọba lati ba dide iranlọwọ ki iwa naa le d'ohun igbagbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI