B'awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara ṣe n ka saara si redio ipinlẹ naa, iyẹn Redio Kwara to bẹrẹ iṣẹ laipẹ yii naa ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq
naa n gbe oṣuba kara f'awọn alakoso at'awọn sọrọsọrọ to wa nibẹ lori iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe.
Ni bayii, ohun ti a gbọ ni pe pẹlu ipele ti rẹdio naa de bayii, oni ti i ṣe Wẹside ni rẹdio naa bẹrẹ iṣẹ aṣeyipo, iyẹna wakati mẹrinlelogun lai dawọ duro, ti yoo si maa lọ bẹẹ titi lai.
Ninu ọrọ Gomina lo ti sọ pe ọkan oun balẹ wi pe redio naa yoo tayọ ju awọn ẹlẹgbẹ rẹ lọ.
Aago mejila aarọ yii ni redio Kwara bẹrẹ iṣẹ naa.
No comments:
Post a Comment