Ọna ara-ọtọ ni Redio ipinlẹ kwara, (Radio Kwara) gba bẹrẹ iṣẹ ori afẹfẹ pẹlu bi Gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq ṣe yan ogbontarigi pedepede n'ipinlẹ naa, Ọgbẹni Kayọde Arẹmu gẹgẹ bi alakoso ileeṣẹ redio na.
Eyi gan an lo mu ki ẹgbẹ awọn akọroyin n'ipinlẹ naa gbe oṣuba kare fun Gomina ipinlẹ naa lori bo ṣe yan ọkunrin naa gẹgẹ bi alakoso, ti wọn si ni AbdulRazaq mu oju lọ s'ọja.
Ninu atẹjade ti alaga ati akọwe ẹgbẹ naa, Malam Umar Abdulwahab ati Dcn. Ọmọtayọ Ayanda fi sita lati fi ṣe sadankata fun gomina ni wọn ti sọ pe ẹni to kaju oṣuwọn n'ijọba yan naa.
Wọn gba Arẹmu lamọran lati lo imọ ati ẹkọ to ni n'idi iṣẹ iroyin ati igbohunsafẹfẹ fi gbe redio naa larugẹ.
No comments:
Post a Comment