ỌWỌ TẸ OLUKỌ ILE-ẸKỌ ALAKỌBẸRẸ, ỌGA BANKI PẸLU AGBẸJỌRO LORI ẸSUN JIBITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 20, 2020

ỌWỌ TẸ OLUKỌ ILE-ẸKỌ ALAKỌBẸRẸ, ỌGA BANKI PẸLU AGBẸJỌRO LORI ẸSUN JIBITI


Ahamọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti asilo owo, iyẹn Independent Corrupt Practices and Other Related Offences Commission (ICPC) ni ọkann lara awọn olukọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ kan, Roseline Uche Egbuha, alakoso banki kan at'awọn oṣiṣẹ abẹ rẹ pẹlu agbẹjọro banki wọn lori ẹsun jibiti owo.

Owo naa ti ko din ni ẹẹdẹgbẹta le laadọta (550m) miliọnu naira la gbọ pe awọn eeyan naa ko jẹ, ti wọn si ni inu apo ile ifowopamọsi Roseline lowo naa de si, n'ipinlẹ Anambra.

Agbẹnusọ fun ajọ ICPC, Rasheedat Okoduwa nilu Abuja lo f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade to gbe sita laarọ ana ti i ṣe Fraide.

Wọn ni ninu oṣu kẹsan-an ọdun to kọja, iyẹn 2019 l'aṣiri Roseline tu pẹlu owo naa, ti wọn si f'oju rẹ ba ile-ẹjọ lati sọ bi owo naa ṣe jẹ, ti wọn si lo o sọ pe ọmọ oun lo ni owo naa, ṣugbọn ti wọn ko ri ọmọ naa.

Latigba naa la gbọ pe wọn ti gbejile apo ifowopamọsi rẹ pe ko nii le gba owo jade nibẹ, ayafi ki owo wọle, ti wọn si loo gbe ajọ naa lọ si kọọtu lati tu apo ifowopamọsi rẹ silẹ.

Ni iwadii siwaju si i l'aṣiri tun ti tu wi pe alakoso banki naa, Chisomaga Daly-Okoro, at'awọn oṣiṣẹ banki naa bii Beckley Ojo, Sarah Ugamah ati agbẹjọro wọn, Nsikak Udoh.

Ohun ti wọn loo jẹ ki aṣiri naa tu sita ni bi wọn ṣe ṣakiyesi pe wọn ti fi owo naa ranṣẹ sinu apo ile ifowopamọsi ẹnikan ti wọn pe ni Ferdinand Isa l'ọjọ kẹrin oṣu yii, ti wọn si loo lọwọ awọn tọwọ tẹ ni banki yii ninu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI