L'ọjọ Ajẹ, iyẹn Mọnde ana n'ijọba ipinlẹ Ọyọ paṣẹ pe ki awọn ileewe ati ile ijọsin kaakiri
ipinlẹ naa ṣilẹkun wọn silẹ fun ijọsin, bẹrẹ lati ọjọ Aje-Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu yii.
Igbimọ amuṣẹya ti ijọba ipinlẹ Ọyọ gbe kalẹ lori
kikoju ajakalẹ arun koronafairọọsi lo kede igbesẹ ijọba ipinlẹ naa sita.
Ijọba ipinlẹ Ọyọ ni awọn akẹkọọ iwe kẹfa nile-ẸKỌ
alakọọbẹrẹ (Primary Six), iwe kẹta ile-ẹkọ girama (JSS 3) ati kilasi aṣekagba
nile-ẹkọ girama (SSS 3) nikan ni yoo wọle ikẹkọọ ni ọjọ naa ti wọn si gbọdọ maa
tẹle awọn ilana ti igbimọ amuṣẹya naa ba fi silẹ.
Nigba to n sọrọ nipa t'awọn ile ijọsin, O ni awọn ile-ijọsin pẹlu
le bẹrẹ sii ṣ'ilẹkun wọn silẹ fun ijọsin lati ọjọ Aje kan naa, ṣugbọn to ni ida kan
ninu mẹrin awọn eeyan to n wa si ile-ijọsin naa tẹlẹ ni aye gba lati maa jọsin
fun asiko yii.
Bẹẹ lo ni wọn ko gbọdọ ṣai tẹle ofin ati ilana igbimọ amuṣẹya naa.
No comments:
Post a Comment