B'eeyan ba gun ẹṣin ninu awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara l'asiko yii, koda, ẹni naa ko nii kọ'sẹ rara nitori pe ṣẹkẹn bayii ninu gbogbo araalu n dun lori omi-ẹrọ igbalode to tun balẹ gudẹ saarin ilu.
Lati bi ọdun mẹtadinlogun ṣeyin la gbọ pe awọn akanṣe omi t'ijọba tẹlẹri, iyẹn iṣakoso Mohammed Lawal, eyi ti wọn pe ni 'Up Lawal' ṣe laṣe pati n'ijọba AbdulRazaq ti sọji pada.
Ko din agbegbe mọkanla ti wọn ṣe ibudo omi, iyẹn reservoir si n'ijọba ti dawọ le, ti won si ti pari rẹ bayii.
Lara awọn agbegbe naa ni; Sango, Surulere,
Adangba, Kongbari, Idi-Ape, Ogidi, Oke-Apomu, Balogun, Ajikọbi, Isalẹ Koko ati
Senni.
No comments:
Post a Comment