Lónìí ọjọ́ Àìkú tíì ṣe Sande nijọba ipinlẹ Kwara tú àwọn mẹjọ tí wọn tí wá lábẹ́ ààbò itọju àrùn koronafairọọsi silẹ State
A gbọ pé lẹ́yìn tí àyẹ̀wò méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fìdí rẹ múlẹ̀ pé kò sí nǹkan tó ń jẹ àrùn náà mọ lára àwọn èèyàn náà lo mú kí ẹka eto ìlera sọ pé wọn peregede láti máa lọ sile.
Ní báyìí, àwọn mejilelaadọta ni wọn ti gba òmìnira kúrò nínú àrùn náà.
AWIKONKO tún gbọ pé lónìí ní wọn tún ṣàwárí àwọn márùn-ún mi-ín tí wọn tí ni àrùn yìí, tí àkọsílẹ̀ àwọn tó nù àrùn náà tí di mejilelaadọjọ {132}.
Awon mọkandinlọgọrin ni wọn ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ báyìí, gẹgẹ bí a ṣe gbọ.
No comments:
Post a Comment