OKOLI TO F'IPA JA IBALE ỌMỌ ỌDUN MẸWAA DERO ATIMỌLE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 24, 2020

OKOLI TO F'IPA JA IBALE ỌMỌ ỌDUN MẸWAA DERO ATIMỌLE


Atimọle ọlọpaa ni gendekunrin ẹni ọdun mejilelogun ti ẹ n wo yii, Ikechukwu Okoli wa bayii, nibi to ti n kawọ pọyin rojọ lori ọmọdun mẹwaa to f'ipa ja ibale rẹ.

Ni nnkan bi aago mẹta ọsan ọjọ Mọnde to kọja yii lọwọ tẹ Okoli, ọmọ bibi abule Ndilionwu to wa n'ijọba ibilẹ Orumba North, ṣugbọn to n gbe ladugbo Uzoegwu, Nkpor, iyẹni n'ijọba ibilẹ Idemili North, ipinlẹ Anambra.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Anambra, SP Haruna Mohammed ṣe sọ, o ni b'awọn ṣe gba ẹsun naa l'awọn ti lọ gbe Okoli nile, t'awọn si tun ṣayẹwo fun ọmọ naa lọsibitu, nibi ti wọn ti f'idi rẹ mulẹ.
Kọmiṣanna ọlọpaa, John B. Abang ti sọ pe ki ẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ iwadii awọn ọdaran gba iṣẹ naa ṣe, ki wọn le tubọ ri awọn ẹridaju lati fi gbe Okoli lọ sile-ẹjọ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI