O ṢẸLẸ! Ẹ GBỌ NNKAN TI BUHARI ỌMỌ MUSA SỌ NIPA GOMINA ABDULRAZAQ T'IPINLẸ KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 16, 2020

O ṢẸLẸ! Ẹ GBỌ NNKAN TI BUHARI ỌMỌ MUSA SỌ NIPA GOMINA ABDULRAZAQ T'IPINLẸ KWARA

Kii ṣe akọkọ ree t'awọn eeyan yoo maa gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara lori awón akanṣe iṣẹ to dawọ le, eyi to fi n sọ Kwara d'ọtun.

Laipe yii ni ọkan lara awọn gbajugbaja Alfa oniwaasi agbaye nni, Sheik Buhari Ọmọ Musa sọrọ iyalẹnu n'ipa awọn iṣẹ idagbasoke ti AbdulRazaq n ṣe kaakiri ipinlẹ naa.

O ni l'ọdun diẹ sẹyin, oun mọ bi ipinlẹ Kwara ṣe wa, iyẹn n'igba aye awọn ijọba to kọja lọ, ṣugbọn ni bayii, afọju gan-an mọ pe nnkan ti yi pada, ko digba ti wọn ba ṣẹṣẹ n sọ fun un.

Ninu fọnran kan to tẹ AWIKONKO lọwọ, iyẹn nibi ti Ọmọ Musa ti n sọrọ lo ti sọ pe l'ọjọ kan loun n jade lọ pẹlu awọn eeyan oun, o ni bi ẹni to wa mọto naa ṣe ya s'ibi kan ti ko s'ọna nibẹ tẹlẹ niyẹn, o loju ẹsẹ loun ti sọ pe ko sọna nibẹ, ṣugbọn ti wọn jẹ ko ye oun pe ọna ti wa nibẹ.

O ni kani o ṣee ṣe ki eeyan kan ṣoṣo maa ṣe ijọba lo titi lai ni, awọn ki ba sọ pe ki Gomina AbdulRazaq maa ba iṣẹ naa lọ nitori pe iyalẹnu ni ọrọ rẹ ṣi n jẹ f'ọun pẹlu awọn akanṣe iṣẹ naa, to si lo ti n la ipinlẹ naa loju kọja sisọ.

Fidio naa ree


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI