Ijọba ipinlẹ Eko labẹ Gomina Babajide Sanwo-Olu ti sọ pe ki i ṣe pe Gomina ana n'ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi deedee ku, bi ko ṣe pe aisan ara rẹ ko gboogun mọ, ati pe awọn ẹya ara rẹ ko gba oogun mọ.
Kọmiṣanna f'eto ilera n'ipinlẹ naa, Ọjọgbọn Akin Abayọmi lo f'idi ọrọ naa mulẹ loni, Fraide wi pe ṣe ni gbogbo ẹya rẹ da iṣẹ silẹ lasiko to n gba itọju lọwọ, eyi ti ko jẹ ko ye lọwọ iku.
O ni arun koronafairọọsi ti Ajimọbi kagbako rẹ lo mu ki awọn ẹya rẹ da iṣẹ silẹ, paapaa nitori awọn aisan to ti wa lara rẹ tẹlẹ, eyi to tun ran iku ẹ lọwọ.
AWIKONKO gbọ pe bo tilẹ jẹ pe ori pada ko Ajimọbi yọ lọwọ arun Covid-19 naa, ṣugbọn ṣe lo tun da kun ilera ara rẹ.
Awọn ẹrọ igbalode to n gbe ẹmi duro la gbọ pe wọn fa si Ajimọbi lara lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn to pada gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra lọjọ Tọside ana.
No comments:
Post a Comment