Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun - Ko din ni maluu mejilelogoji ni wọn ti wa lahamọ ẹgbẹ aabo tilẹ Yoruba nni, iyẹn Amọtẹkun pẹlu bi wọn ṣe fẹsun kan wọn wi pe wọn ti jẹ gbogbo ire oko oloko.
Awọn oko oloko to wa lagbegbe Alagbaka Extension n'ilu Akurẹ, ipinlẹ Ondo la gbọ pe awọn Fulani darandaran ko awọn amaluu wọn naa jẹ patapata.
Kọmanda ẹgbẹ Amọtẹkun n'ipinlẹ Ondo, Adetunji
Adelẹyẹ lo f'idi rẹ mulẹ f'awọn oniroyin laipẹ yii pe awọn maluu naa ti wa nibi ti wọn yoo ti gba idajọ to tọ si wọn.
Adelẹyẹ sọ pe awọn agbẹ to da oko yii ni wọn wa fi ẹjọ sun awọn, t'awọn si dide lati ṣe iwadii, to si ni lẹyin iwadii l'awọn rii pe oko mẹjọ ọtọọtọ ti wọn gbin agbado, ẹgẹ(paki) l'awọn Fulani naa fi maluu wọn jẹ patapata.
O ni eyi to n jẹ iyalẹnu ni pe ṣe l'awọn Fulani yii tun yọ ibọn ati ida ọwọ wọn s'awọn to ni oko naa, eyi to mu wọn na papa bora, ki wọn to fi awọn maluu wọn jẹ gbogbo ire oko naa tan.
Adetunji sọ pe n'igba t'awọn de ori oko naa nibi t'awọn darandaran yii wa, ṣe ni wọn kọju ija si wọn, ṣugbọn nitori imọ ẹkọ aabo t'awọn ni lo jẹ k'ọwọ pada tẹ wọn.
No comments:
Post a Comment