Ó PARÍ! ILÉ-ẸJỌ́ TRIBUNAL DA ẸJỌ́ DINO MELAYE NU, WỌN NI KÒ LẸSẸ NÍLẸ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 10, 2020

Ó PARÍ! ILÉ-ẸJỌ́ TRIBUNAL DA ẸJỌ́ DINO MELAYE NU, WỌN NI KÒ LẸSẸ NÍLẸ̀


Ilé-ẹjọ Tiraibuna {Tribunal}to fikalẹ silu Abuja ti da ẹjọ kotẹmilọrun tí Sẹnetọ Dino Melaye pé láti tako idibo tó gbé Sẹnetọ tó ń ṣojú ẹkùn Kogi West nílé igbimọ aṣofin àgbà orílẹ̀-èdè yìí, Sẹnetọ Smart Adeyẹmi wọlé l'ọdun 2019.

Lónìí tíì ṣe Wẹside ni ile-ẹjọ náà sọ pé ẹjọ tí Sẹnetọ àná nipinlẹ náà, Melaye pé kò lẹsẹ nílẹ̀ rárá, nítorí náà o sọ pe ohun dá ẹjọ náà nù sigbo.

Ilé-ẹjọ́ náà tí Onidajọ Kashim Kaigama dárí ẹ lo dá ẹjọ náà ni, wí pé kò fi ẹsẹ múlẹ̀ tó, ìdí rèé tó fi làwọn kò tún lè máa ṣe wàhálà lórí rẹ. 

Ó ní gbogbo àwọn ẹ̀rí tí wọn kò wá láti fi tako ìdìbò tó gbé Sẹnetọ Smart Adeyẹmi wọlé nínú atundi ibo ní kó fẹsẹ múlẹ̀ rárá, àti pé kò sí awuruju tàbí apọju ìbò nínú idibo náà.
 
Ninu oṣù kọkànlá ọdún tó kọjá ní àjọ eleto ìdìbò kéde Sẹnetọ Smart gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jawe olubori nínú atundi ibo tó wáyé. 

Ibo 88,373 ni Sẹnetọ Smart ni, nígbà tí Sẹnetọ Dino Melaye ni ibo 62,133, èyí tí Melaye sọ pé kò tẹ òun lọrun, tó sì gba ile-ẹjọ lọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI