Bi aṣiri to lu sita nipa bi Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ṣe n bẹ Aarẹ ilẹ Cihna Xi Jinping fun iranlọwọ lati pada sipo Aarẹ lẹẹkeji ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe aaye lati de ipo naa lẹẹkeji kere gidi.
L'Ọjọru tii ṣe Wẹside ana ni oludamọnran lori ọrọ aabo nilẹ Amẹrika tẹlẹ, John Bolton tu aṣiri naa sita wi pe loootọ Aarẹ Donald Trump rawọ ẹbẹ fun iranlọwọ lati pada sipo naa lẹẹkeji si Aarẹ Xi Jinping.
Ọkunrin naa sọ pe nibi apeero kan to waye l'oṣu kẹfa ọdun to kọja ni Aarẹ Trump bẹbẹ naa.
O ni pẹlu imọ tara-ẹni-nikan ni Trump fi yi apeero naa si ipolongo ibo, nibẹ lo si ti fi ọgbọn sọ fun Xi pe ko lo ipo rẹ lati jẹ k'oun wọle lẹẹkeji.
Lara awọn iwe iroyin to gbe ọrọ naa ni The Washington
Post, The New York Times ati The Wall Street Journal.
No comments:
Post a Comment