O MA ṢE O! WỌN TI RI OKU AISHAT TI AGBARA-OJO GBE LỌ L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 24, 2020

O MA ṢE O! WỌN TI RI OKU AISHAT TI AGBARA-OJO GBE LỌ L'EKOO


Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri n'ipinlẹ Eko, Lagos State Emergency Management Agency (LASEMA) ti kede sita wi pe awọn ti ri oku ọmọbinrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Aishat ti agbara-ojo gbe lọ l'ọjọ Aje, Mọnde ijẹta lagbegbe Surulere.

Alakoso ajọ naa, Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu lo f'idi iṣẹlẹ yii mulẹ wi pe lẹyin iṣẹ takuntakun t'awọn ṣe lo jẹ k'awọn pada ri oku ọmọbinrin naa lagbegbe Onilegogoro.

L'ọjọ Mọnde naa la gbọ pe Aishat ko sinu koto nla kan to wa lẹgbẹ Surulere Plaza lasiko to n wa ọna lati de ibi to n lọ, ṣugbọ ti ẹsẹ rẹ yọ sinu koto naa.

Gbogbo akitiyan awọn to wa lagbegbe naa lasiko iṣẹlẹ yii lati doola ẹmi Aishat lo ja si pabo, to si jẹ pe loju ẹsẹ ni wọn ti ke gbajare si ajọ LASEMA fun iranlọwọ.

Nnkan bi aago mẹjọ aabọ aarọ ana, Tuside la gbọ pe wọn pada ri oku Aishat lẹgbẹ koto nla kan to wa lagbegbe Onilegogoro ni Surulere naa, ti wọn si ti n sin in sibẹ loju ẹsẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI