Gómìnà Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Èkó tí sọ pé kò tíì tó àsìkò láti ṣí àwọn ilẹ̀kùn ilé ìjọsìn bíi ṣọọṣi àti mọṣalaṣi silẹ, nítorí pé ṣe ni itankalẹ àrùn COVID-19 tún ń pọ̀ sii, kàkà kó dínkù.
Lónìí ní Gómìnà Sanwo-Olu sọ̀rọ̀ náà síta lásìkò tó ń b'awọn oniroyin sọ̀rọ̀ nílé ìjọba tó wà ní Marina.
Bẹ ó bá gbàgbé, ṣáájú àsìkò yìí ni ìjọba tí kéde pé ọjọ́ kọkàndínlógún àti ọjọ́ kọkanlelogun oṣù yìí ni mọṣalaṣi àti ṣọọṣi yóò silẹkun láti bẹ̀rẹ̀ sii jọsin.
Ní báyìí, ó ọ̀rọ̀ náà kò níí rí bẹ́ẹ̀ mọ.
No comments:
Post a Comment