NITORI WAHALA PATIGI ATI LAFIAGI, GOMINA ABDULRAZAQ GBE IGBIMỌ NLA DIDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 24, 2020

NITORI WAHALA PATIGI ATI LAFIAGI, GOMINA ABDULRAZAQ GBE IGBIMỌ NLA DIDE

Wọn ni agba ki i wa l'ọja ki ori ọmọ tuntun wọ, bẹẹ si ni Yoruba tun maa n sọ pe onilu ko nii jẹ k'ilu rẹ tu. Wọnyi gan an l'awọn afiwe to lọ n'ibamu pẹlu bi gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ṣe gbe igbimọ ẹlẹni mẹrinla kan dide lati yanju aawọ to n waye laarin awọn ilu meji nni, Patigi ati Lafiagi.

Ọjọ Mọnde to kọja yii la gbọ pe Gomina AbdulRazaq gbe igbimọ naa ti abẹnugọn ile ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa tẹlẹri, Ọnọrebu Benjami Yissa jẹ alaga rẹ dide lati ṣagbeyẹwo gbogbo nnkan to n da wahala silẹ laaarin awọn ilu meji yii.

A gbọ pe awọn araalu yii ko fi oju rere wo ara wọn, koda, ti wọn tun n gbena woju ara wọn lori ọrọ ti ko to nnkan, eyi ti ko tii sẹni to le sọ pato ohun to n da wahala naa silẹ, taa si gbọ pe ọpọlọpọ dukia lo ti ṣofo danu, t'awọn eeyan si ti farapa yannayanna.
 
Gẹgẹ bi atẹjade ti Ọgbẹni Rafiu Ajakaye to jẹ akọwe gomina fi sita lo ti jẹ ko di mimọ pe ọsẹ kan pere ni Gomina AbdulRazaq fi silẹ f'awọn igbimọ naa lati mọ nnkan to n fa wahala gangan, ki wọn le tete pana ẹ ko too di ogun abẹlẹ.

Lara awọn to tun wa ninu igbimọ naa ni Ọnọrebu Musa Guyegi ati Ọnọrebu Adamu Rufai ti wọn jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin; Ọnọrebu Joanah Nnazua Kolo to jẹ kọmiṣanna fun ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ; Ọnọrebu Yinka Aluko, oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ akanṣe iṣẹ; Ọnọrebu Attahiru Ibrahim Abdulkadir, oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ.

Awọn yooku ni Bala Aliyu Likofu; Bala Mahmud; Babo Lata; Izaiah Samuel Mayaki; Onimọ-ẹrọ Saba Umar; Dọkita Johnson Oyeniyi; Raheem AbdulBaki ati S. AbdulGaniyu toun jẹ akọwe igbimọ naa.

A gbọ pe latigba ti ijọba ti bẹrẹ igbesẹ lati pana aawọ naa ni alaafia ti pada jọba l'awọn agbegbe yii, paapaa n'igba t'awọn ileeṣẹ eleto aabo ti wa layika yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI