Ìjọba ipinlẹ Kwara tí fi lẹta ibanujẹ ranṣẹ sì ìdílé gbajugbaja akọroyin nnì, Oloogbe Waheed Bakare, ẹni tó tún jẹ́ Olootu fún ìwé ìròyìn NEW TELEGRAPH tí ọjọ́ Satide.
Ninu atẹjade tí akọ̀wé ìròyìn Gomina ipinlẹ Kwara, Rafiu Ajakaye fi síta nirọlẹ òní Abamẹta, ìyẹn Satide, èyí tó fi bá ìdílé olóògbé náà kẹ́dùn ikú èèyàn wọn lo tí ṣàpèjúwe Waheed gẹ́gẹ́ bí alabaṣiṣẹpọ rere.
Ó ní àdánù ńlá ni ikú Waheed Bakare jẹ fún wọn nítorí pé àwọn kò lè gbàgbé ibaṣepọ tó dán mọnran pẹ̀lú rẹ nígbà ayé ẹ, tó sì tún jẹ́ oludamọran pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn fún pupọ àwọn èèyàn.
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pé gbogbo àwọn akẹgbẹ rẹ, pàápàá agboolé oniroyin, ó tó fi mọ àwọn aráàlú Ajaṣẹ-Ipo ni kò níí gbàgbé rẹ títí lai.
Bẹẹ lo ṣèlérí wí pé àwọn yóò dúró tì mọlẹbi rẹ digbi lẹ́yìn ipapoda ẹ.
No comments:
Post a Comment