Lọjọ Aje, iyẹn Mọnde ij ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun kede Alaaja Sẹlimọt Ọlapeju Ọttun gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ tuntun n'ipinlẹ naa.
Ọjọ Ẹti ti i ṣe Fraide ọsẹ to kọja yii ni olori awọn oṣiṣẹ ijọba tẹlẹ, Arabinrin Amọpe Ajibọla Chokor fẹyinti n'idi iṣẹ ijọba lẹyin ọdun marundinlogoji to ti ṣiṣẹ labẹ ijọba.
Gẹgẹ bi atẹjade ti akọwe gomina lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin fi sita, o sọ pe iṣẹ Alaaja Ọttun ti bẹrẹ l'oju ẹsẹ ti wọn ti kede rẹ.
A gbọ pe Alaaja Ọttun kaju oṣuwọn, to si tun ni akọsilẹ rere lẹnu iṣẹ ijọba, eyi to mu ki wọn yan an gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ ijọba n'ipinlẹ naa.
No comments:
Post a Comment