Ìjọba ipinlẹ Kwara tí kéde síta pé àwọn tí gba owó tí kò dín ni biliọnu mẹ́ta náírà gẹ́gẹ́ bí owó iranwọ, ìyẹn allocation láti ọ̀dọ ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè yìí.
Owo naa N3,092,495,479:52 lo jẹ́ ti oṣù kẹfà ọdún yìí.
Èyí ni bí wọn ṣe gba owó naa:
(Net) statutory revenue allocation of N1,994,859,433.79;
Value Added Tax of N934,174,265.19;
Exchange Gain of N157,102,519.91; ati
Excess Bank Charges of N6,359,260.63.
Yàtọ̀ sí èyí, àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹrindilogun tó wà nipinlẹ náà tún gbà owó tó lè díẹ̀ ni biliọnu méjì náírà, ìyẹn N2,142,342,139.55.
Ṣáájú àsìkò yìí, ìjọba tí san owó tó dín díẹ̀ ni biliọnu mẹ́ta náírà, N2,819,603,697.34 gẹ́gẹ́ bí owó oṣù, owó ifẹyinti, ajẹẹlẹ àti owó iranwọ fáwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga tó fi mọ àwọn ẹka ileeṣẹ ìjọba.
Owo oṣù àti owó ifẹyinti ni wọn loo jẹ́ N2, 256,705,810:18,
Owo ajẹẹlẹ ni wọn pé ni N100,000,000,
N127,067,868.99 ni wọn làwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga gba, nígbà tí wọn san N335,830,018,17 fáwọn ẹka ileeṣẹ ìjọba yòókù.
No comments:
Post a Comment