Bí gbogbo ìjọba, pàápàá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe ń ṣayẹyẹ ayajọ eto òṣèlú awaarawa, Gómìnà ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq tí sọ pé asán ni ìjọba àti òṣèlú alagbada yóò já sí ti ko ba ti sì ìfẹ́ aráàlú lọ́kàn àwọn adarí.
Ana tíì ṣe June 12 ni Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq sọ̀rọ̀ yìí jáde nínú atẹjade tí akọ̀wé ìròyìn ẹ, Rafiu Ajakaye gbé síta.
Ó ní "asán ni òṣèlú awaarawa àti ìjọba alagbada yóò já sí nígbà tí wón bá ń lo ẹtọ àwọn èèyàn kan fáwọn mi-ín"
"Mo darapọ mọ àwọn ajijagbara, pàápàá Ààrẹ láti ṣajọyọ ayẹyẹ òṣèlú awaarawa. Ibẹri mi lọ fáwọn akíkanjú ọkùnrin àti obìnrin tó já takuntakun fún òṣèlú awaarawa, àwọn tó wà láyé àtàwọn tó ti filẹ ṣaṣọbora."
Bẹẹ lo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ àti olùgbé ipinlẹ Kwara fún àṣeyọrí ẹgbẹ́ òṣèlú nínú ìdìbò àpapọ̀ ọdún tó kọjá lọ, tó sì tún ní àwọn àfojúsùn òun ni lati pèsè àwọn ohun amayedẹrun fáwọn aráàlú láti jẹ mudunmudun eto òṣèlú awaarawa náà.
No comments:
Post a Comment