IRỌRUN ÀWỌN AGBẸ NI KWARA, OÚNJẸ Ọ̀PỌ̀ YANTURU FÁWỌN ARÁÀLÚ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 10, 2020

IRỌRUN ÀWỌN AGBẸ NI KWARA, OÚNJẸ Ọ̀PỌ̀ YANTURU FÁWỌN ARÁÀLÚ


Béèyàn bá gùn ẹṣin nínú àwọn ọmọ àti olùgbé ipinlẹ Kwara lásìkò yìí, ó dájú pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò níí kọsẹ lailai, ìyẹn bo ṣe jẹ́ pé inú ìdùnnú àti ayọ̀ ni gbogbo wọn pátápátá wà báyìí lórí oúnjẹ ọ̀pọ̀ yanturu tó fẹẹ ṣẹlẹ̀. 

Òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí nijọba bẹ̀rẹ̀ ifilọlẹ ọ̀nà láti rán àwọn agbẹ káàkiri ipinlẹ náà lọ́wọ́, lórí ọ̀nà láti jẹ ki oúnjẹ pọ rẹpẹtẹ fáwọn aráàlú.

AWIKONKO gbọ pé ìjọba ipinlẹ náà lábẹ́ Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pé irinṣẹ tí wọn fi ń dá oko, ìyẹn tirakitọ {tractor}, èyí tí wọn ń yà lowo tó pò, láwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sii yà wọn lowo yí kò ga ní lára rárá.

Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà nijọba sọ pé ohun yóò máa yà àwọn àgbẹ̀ ni tirakitọ náà, èyí tó fi ẹgbẹ̀rún mẹ́fà náírà dín lowo tí wọn ń yaa tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aladani.


Àádọ́ta làwọn tirakitọ tí a gbọ pé ìjọba gbé silẹ fáwọn àgbẹ̀ náà láti máa yà lo lojoojumọ. 

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ifilọlẹ náà nilu Lafiagi, amugbalẹgbẹ Gómìnà lórí ọ̀rọ̀ àgbẹ̀ àti ọgbin, AbdulQowiy Olódodo sọ pé eto naa wáyé lábẹ́ ohun tí wọn pé ní "Tractorization Subsidy Scheme" láti jẹ ki oúnjẹ pọ rẹpẹtẹ nilu. 

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ipele àkọ́kọ́ rèé láti bẹ̀rẹ̀ iranlọwọ náà fún ẹyin àgbẹ̀, laipẹ a máa tún fun-un yín ní làwọn nnkan ti ẹ nílò bíi èso àti ajilẹ láti mú ọpọ yanturu wá.

"Lara àwọn ìlérí tí Gómìnà AbdulRazaq ṣe lásìkò ìpolongo ìdìbò rèé lọ́dún tó kọjá, ìyẹn iranlọwọ fáwọn àgbẹ̀. Ẹlẹẹkeji ni pé a ń bẹ̀rẹ̀ eto yìí lásìkò yìí nítorí taa nigbagbọ pé àsìkò tí àrùn COVID-19 wá níta yìí, ó ṣeé ṣe kí oúnjẹ hán, èyí ni ọ̀nà tí a tún lérò wí pé yóò jẹ ki oúnjẹ pọ láwùjọ wá."


Lára àwọn tó tún wà nibẹ lọ́jọ́ náà ni: amugbalẹgbẹ pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ ìpèsè iṣẹ, Alhassan Aliyu; Dọkita Jamila Bio-Ibrahim àtàwọn mi-ín.

Ọ̀kan lára àwọn àgbẹ̀ ni Lafiagi, Muhammad Shaaba Lafiagi dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ ìjọba ipinlẹ náà fún bí wọn ṣe mú ìlérí ṣẹ, pàápàá lásìkò tí nnkan kò rọrùn yìí. Bákan náà lo sọ pé irú àǹfààní báyìí tí pẹ tó ti waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI