ILÉÈWÉ, ILÉ IJỌSIN LA MÁA ṢI SÍLẸ̀ GBẸYIN - MAKINDE RỌ ÀWỌN OLÓRÍ ẸLẸ́SÌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 10, 2020

ILÉÈWÉ, ILÉ IJỌSIN LA MÁA ṢI SÍLẸ̀ GBẸYIN - MAKINDE RỌ ÀWỌN OLÓRÍ ẸLẸ́SÌN


Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọ̀yọ́ tí rawọ ẹ̀bẹ̀ sì gbogbo àwọn olórí ẹlẹ́sìn pátápátá káàkiri ipinlẹ náà láti túbọ̀ ṣe sùúrù dáadáa, nítorí pé ilé ìjọsìn wa lara àwọn ibùdó táwọn yóò ṣí gbẹyin.

Lonii ni Gómìnà Ṣeyi Makinde sọ̀rọ̀ náà lónìí ní nílé igbimọ aṣofin ipinlẹ náà wí pé àwọn èèyàn ti ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ kẹẹdogun oṣù yìí wí pé ìjọba yóò pàṣẹ ṣíṣí ilé ìjọsìn, tó sì ni àwọn ko tii lè sọ bóyá yóò rí bẹ́ẹ̀ mọ.

Ó ní bí nnkan bá ṣe rí ní yóò sọ bóyá àwọn yóò ṣí àwọn ilé ìjọsìn àtàwọn iléèwé silẹ, àti pé ohun táwọn ọjọgbọn lẹka eto ìlera bá ti sọ làwọn yóò tẹle.

Bakan naa lo tún sọ pé bí àrùn aṣekupani koronafairọọsi ṣe ń tàn káàkiri ń kan ìjọba lominu, èyí gan-an ni kò tíì jẹ́ káwọn mọ igbesẹ tó kàn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI