Titi di asiko ti a kọ iroyin yii tan ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo ṣi n ṣe iwadii lati mọ ẹni (awọn) to pa baba arugbo ẹni ọdun marundinlọgọta (55) kan, Patrick Uchenwoke saarin ọna.
Agbegbe kan ti wọn pe ni Ahaba Orodo, ipinlẹ Imo n'iṣẹlẹ naa ti waye l'ọjọ Mọnde ijẹta.
Ko ti i sẹni to le sọ pato awọn to pa Patrick, bẹẹ ni ko ti i sẹni to le sọ pato idi ti wọn ṣe pa ọkunrin naa danu lori kẹkẹ rẹ titi di asiko ta a kọ iroyin yii tan.
No comments:
Post a Comment