Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara naa ti pẹlu awọn gomina to fi lẹta ibanikẹdun iku gomina ana n'ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi ranṣẹ si idile rẹ ati ijọba ipinlẹ Ọyọ.
O ni ibanujẹ nla ni iku Ajimọbi jẹ fun awọn ara Ọyọ, paapaa orilẹ-ede Naijiria, to si n gbadura pe ki Allah tẹ ẹ si afẹfẹ rere.
“Iku Sẹnetọ Isiaka Abiọla Ajimọbi jẹ adanu nla fun idile ẹ, ijọba APC ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Ọyọ, paapaa orilẹ-ede Naijiria. Akikanju eeyan ni Ajimọbi, ẹni to n gbe orukọ Naijiria larugẹ, to si fi ara jin lati sin awọn eeyan."
O ni ọrẹ oun bi mọlẹbi oun ni Sẹnetọ Ajimọbi, to si sunmọ idile oun daadaa, to si loun ko le gbagbe ẹ titi lai nitori pe oludamọran gidi ni.
No comments:
Post a Comment