IFIPABANILOPỌ! AWỌN MEJILELOGOJI F'OJU BA ILE-ẸJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 20, 2020

IFIPABANILOPỌ! AWỌN MEJILELOGOJI F'OJU BA ILE-ẸJỌ


Awọn ti ko din ni mejilelogoji (42) la gbọ pe wọn ti fi oju ba ile-ẹjọ n'ipinlẹ Kano lori ẹsun ifipabanilopọ to n ja rain-rain kaakiri orilẹ-ede Naijiria lasiko yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa lo tu aṣiri yii sita l'Ọjọbọ, Tọside ijẹta wi pe o ti pẹ t'awọn ti n ri iru awọn ẹsun yii gba n'ipinlẹ naa bẹrẹ lati oṣu kinni ọdun 2020, to si l'awọn kii fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa.

Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa, Abdullahi Kiyawa sọ pe awọn t'iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si l'awọn ti ṣayẹwo fun, ti wọn si ti ko wọn kuro l'ọsibitu.
Kiyawa sọ pe akọsilẹ t'awọn ṣe fi han pe ida mẹtalelọgbọn ninu ẹ lo waye nile akọku, ti ida mẹtadinlogun si waye ninu oko, t'awọn yoo ku si waye nibo mi in.

O wa gba gbogbo obi ati alagbatọ lamọran lati maa tọju awọn ọmọ daadaa, ki wọn si ri daju pe wọn ko f'awọn ọmọ wọn silẹ f'awọn ti wọn ko le jẹri rẹ. Bẹẹ lo ni ki wọn ma ṣe bo ẹnu lati maa fi to ọlọpaa leti bi iru awọn iwa yii ba ṣẹlẹ lagbegbe wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI