Awọn akẹkọọjade ileewe girama t'ilu Ilọrin, iyẹn Ilorin Grammar School ti gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori idagbasoke alaragbayida to n mu ba eto-ẹkọ n'ipinlẹ naa.
Laipẹ yii l'awọn igbimọ awọn akẹkọọjade, iyẹn Old Students n'ile-ẹkọ naa fi imọ-riri wọn han si Gomina AbdulRazaq lori bo ṣe tun awọn kilaasi to ti dẹnukọlẹ kaakiri inu ọgba ile-ẹkọ naa ṣe.
Ile-ẹkọ girama Ilọrin la gbọ pe o wa lara awọn ile-ẹkọ ọgbọn t'ijọba Kwara bẹrẹ atunṣe lori wọn, ti wọn si ti fẹẹ pari bayii.
Ọna lati jẹ ki eto-ẹkọ wa ni irọrun f'awọn akẹkọọ, ati ọna lati jẹ káwọn ọmọ ti wọn ko si nile-ẹkọ pada n'ijọba dawọle yii.
No comments:
Post a Comment