GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ B'ÀWỌN MÙSÙLÙMÍ KẸDUN IKÚ KHALIFAH AL-ADABY - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 13, 2020

GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ B'ÀWỌN MÙSÙLÙMÍ KẸDUN IKÚ KHALIFAH AL-ADABY


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq tí bá ìdílé àti àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí nipinlẹ náà kẹ́dùn ikú Khalifah al-Adaby, Sheikh Ahmad Ọlayiwọla Kamaldeen Al-Adaby to d'olóògbé laipẹ yìí. 

Ninu lẹta ibanikẹdun tí Gómìnà AbdulRazaq bù ọwọ lu, èyí tí akọ̀wé Gómìnà lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Rafiu Ajakaye fi síta lo tí sọ pé àdánù ńlá ni ikú Sheikh Kamaldeen Al-Adaby jẹ́ fún gbogbo Mùsùlùmí.

O ni òjìji ni ìròyìn ikú náà bá òun, tó sì jẹ ẹ̀dùn ọkàn pé àgbà musulumi náà jáde láyé lásìkò yìí. 

Gómìnà AbdulRazaq gbàdúrà fáwọn ẹbí náà pé Ọlọ́run kò níí ṣe ikú náà ni akufa, àti pé Ọlọ́run yóò tẹ olóògbé náà sì afẹ́fẹ́ rere. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI