Tiro yẹ lójú òpó, erin ṣubú kò lè dide
Lónìí ní Gómìnà àná nipinlẹ Ọ̀yọ́, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi fi ilẹ̀ ṣe aṣọbora ninu ile ẹ tó wà ní ojúlé kẹfà, àdúgbò Yemọja, Oluyọle, ìlú Ìbàdàn.
Ṣe làwọn èèyàn ń gbé ara wọn ṣanlẹ gidigidi, tí wọn ń wá ẹkún mu nígbà tí wọn gbé òkú Ajimọbi wọ agbègbè naa.
Aago mẹ́wàá àárọ̀ òní, 10:05am ni wọn gbé òkú Ajimọbi sínú kòtò.
Pẹ̀lú ìdí gágá àwọn òṣìṣẹ́ alaabo ni wọn fi sìnkú olóògbé náà, ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà COVID-19.
No comments:
Post a Comment