Awọn ‘Baba Isalẹ’ ni eto oṣelu Naijiria ni
ọpọlọpọ eniyan gbagbọ wi pe wọn kii dije dupo fun ara wọn, amọ awọn ni o ma n
sọ nipa ẹni ti yoo bori tabi ti yoo kuna ni idibo sipo lagbeegbe wọn.
Gẹgẹ bi eto idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ondo ati
ipinlẹ Edo ṣe ti n sun mọle bayii, awọn Baba Isalẹ yii ni wọn n sọ bi o ṣe
maari.
Awọn Baba Iṣalẹ yii ni wọn ma n lo owo ati ipọ
wọn lati fi gbaruku ti ẹni ti wọn ba tilẹyin ninu ididbo naa.
Awọn eniyan lo gbagbọ pe ẹni to ba ni Baba isalẹ
ninu ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria ni anfaani lati dije dupo ti wọn yoo si bori, bi
wọn ko tilẹ ni ọpọlọpọ imọ nipa oṣelu.
Saaju idibo sipo gomina ni ipinlẹ Edo ni Osu
Kẹwa, Odun 2020, ohun to gba ẹnu awọn eniyan kan ni ija to bẹ silẹ laarin Adam
Oshiomọlẹ ati Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki.
Ni ọdun 2016 ni Obaseki dede yoju si gbagede
oṣelu Naijiria lẹyin ti Adam Oshiomole gbe e wa lati ilu Eko nibi ti o ti n
ṣiṣẹ, ti ọpọ eniyan ko si mọ ọ ni gbagede oṣelu ipinlẹ Edo.
Iroyin gbe e wi pe lasiko idibo sipo gomina ni
ọdun 2016 naa ni Gomina Adam Oshiomole gbe ipolongo rẹ kari, ti o si n logun rẹ
fun awọn eniyan nigba naa lati tako Pasito Osagie Ize-Iyamu to n dije dupo
gomina lẹgbẹ oṣelu PDP.
Nibayii, ti ọdun mẹrin miran ti de, ọpọlọpọ nkan
ti yi pada, Adam Oshiomọle ti le Obaseki kuro lẹgbẹ Oṣelu APC lẹyin ti o fi
lede wi pe oun naa fẹ dije dupo gomina fun saa keji lẹgbẹ oṣelu APC.
Ibaṣepọ laaarin awọn mejeeji ti fori sanpọn, ti
Obaseki si ti mura lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣẹlu PDP.
Ambode ati Tinubu
Ohun itiju lo jẹ fun Gomina ipinlẹ Eko, Akinwumi
Ambode lasiko idibo sipo gomina ni ipinlẹ Eko lọdun 2019 nigba ti baba isalẹ
rẹ, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu na ọwọ Babajide Sanwo-Olu sọke gẹgẹ bi oludije
sipo gomina ni ipinlẹ Eko lẹyin to ni ki Ambode lo rọkun nilẹ lẹyin ọdun mẹrin
to lo nipo.
Amọ, ohun ti awọn eniyan sọ ni pe, bi Tinubu ṣẹ
na ọwọ rẹ soke ni idibo sipo gomina lọdun 2016 lasiko ti ko si ẹni to mọ ọ
rara, ti ko tilẹ di ipo ọṣelu kankan mu tẹlẹ ki o to di igba naa.
Nigba naa, gomina to wa nibẹ, Babatunde Fashola
fẹ ki kọmisọnna fun eto idajọ nipinlẹ naa, Supo Shasore dije dupo sipo gomina
lasiko naa, amọ Tinubu kọ jalẹ pe Ambode ni yoo ṣe gomina naa pẹlu gbogbo
agbara rẹ.
Ọdun 2019 ni idibo gbogboogbo naa ni Babajide
Sanwo-Olu naa fi idi Ambode janlẹ ninu idibo abẹlẹ saaju idibo sipo gomina naa,
amọ Ambode si wa ni ẹgbẹ oṣelu APC.
Baba isalẹ Adedibu ati Ladoja
Rashidi Ladoja jẹ gomina ipinlẹ Oyo ni ọdun 2003
si ọdun 2007, ti Adedibu si ṣe agbatẹru fun Ladoja gẹgẹ bi oludije lẹgbẹ oṣelu
PDP ni ọdun 2003, ti o si ran an lọwọ lati bori.
Ladọja fun ara rẹ fi idi ẹ mulẹ fun ajọ ajafẹtọ
ọmọniyan, Human RIghts Watch pe Adedibu ṣe bẹbẹ lasiko idibo lati jẹ ki o bori
idibo naa.
Amọ o ni bi oun ṣe wole ni o gbe igbesẹ lati gba
ara rẹ lọwọ Adedibu, ti oun ko si tẹle awọn ilana rẹ mọ.
Ladọja ni oun kọ lati jẹ ki Adedibu lu owo ipinlẹ
naa ni ponpo lẹyin ti Adedibu ni ki oun maa fi ida marundinlọgbọn owo Security
vote to to miliọnu marundinlogun Naira si apo oun ni oṣoosu.
Bakan naa ni Ladoja kọ lati jẹ ki Baba iṣalẹ rẹ
fi orukọ silẹ fun awọn Kọmisọnna ti wọn yoo jọ ṣe ijọba.
Ninu ọrọ tirẹ, Adedibu ni alaamọrẹ ẹda ni Ladọja,
ti o si saa gbogbo ipa rẹ lati jẹ ki o kuro nipo gomina nipinlẹ naa, amọ o lo
saa rẹ tan, idibo miran ni ko bori ninu rẹ mọ.
Ganduje ati Kwankwaso
Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje naa ti pin
gaari pẹlu baba isalẹ rẹ, Rabiu Kwankwaso to ṣe agbatẹru fun un lasiko idibo
sipo gomina ni ọdun 2016.
Ganduje sọ wi pe idi ti oun fi yapa kuro labẹ
Kwankwaso ni pe o jẹ ẹni ti imọtara ẹni nikan n da laamu.
O fẹsun kan an wi pe nitori o jẹ baba isalẹ fun
awọn, o fẹ gaba lẹ wọn lori, ki o si sakoso gbogbo nkan to n wọlẹ si ipinlẹ naa
fun ara rẹ nikan.
Amọ, Kwankwanso naa lo fa ọwọ rẹ soke ni idibọ
ọdun 2016.
Godswill Akpabio lati Udom Gabriel Emmanuel
Ọpọlọ̀pọ eniyan lo gbagbọ wi pe Godswill Akpabio
ni baba isalẹ fun wọn ni ipinlẹ Akwa Ibom. Amọ ija to de lorin di owe laarin
Gomina ipinlẹ naa, Udom Gabriel ati Akpabio lẹyin to kuro ni ẹgbẹ oselu PDP lọ
si ẹgbẹ oṣelu APC.
Ohun to han gbangba ni si awọn eniyan pe Udom di
gomina ipinlẹ Akwa Ibom nitori ibaṣepọ rẹ pẹlu Baba isalẹ Akpabio ti o gbe le
ejika lati dije dupo gomina ni ọdun 2015 to si yege.
Amọ ni bayii wọn ko foju rinju mọ lẹyin ti Udom
yẹba fun Akpabio, eleyii to fa gbọnmi si omi o to laaarin wọn, ki wọn to pin
garri, ti Akpabio si fi PDP silẹ lọ si APC.
Lati BBC
No comments:
Post a Comment