BBC Yorùbá ṣe
àkójọpọ̀ àwọn òṣèré tíátà Yorùbá márùn-ún tó bí ìbejì.
Ipo pataki
ni Yoruba to ibeji si ninu awọn ọmọ nitori orisa ni wọn ka wọn si, ti wọn si
maa n gbe wọn larugẹ.
Koda
oniruuru oriki lo wa fun awọn ibeji nilẹ Yoruba, wọn a pe wọn ni Ejirẹ eyilaki,
ẹdunjọbi agbe ori igi reterete, ọkan ni n ba bi, eyi lo wọle tọ mi, wini-wini
loju orogun, eji wọwọ loju iya rẹ.
Ohun ayọ ati
idunnu lo maa n jẹ ti idile kan ba bi ibeji, ti gbogbo ẹbi yoo si maa du wọn
gbe lọtun losi.
Bẹẹ si ni ọrọ
ri lagbo awọn oṣere tiata naa, idi si ree ti BBC Yoruba fi ṣa awọn oṣere tiata
to bi ibeji sọtọ, lati fi to yin leti.
Awọn oṣere
tiata to bi ibeji:
Femi Adebayo:
Gbajumọ oṣere
tiata lede Yoruba ni Femi Adebayo, ọwọ baba rẹ, Adebayo Salami taa mọ si Ọga
Bello, si lo ti jogun iṣẹ ere ṣíṣe.
Igba meji ni
Femi ti ṣe igbeyawo, iyawo akọkọ rẹ, ti wọn ti kọ ara wọn silẹ Khadijat, si lo
bi ibeji naa fun, pẹlu ọmọdebìnrin kan miran, ti wọn fi jẹ ọmọ mẹta ti obìnrin
naa bi.
Orukọ awọn
ibeji Femi Adebayo ni Fadlullah ati Fadlulrahman Adebayo, awọn mejeeji jọ ara wọn
bii imumu, ti wọn si rẹwa ni ọmọkunrin.
Funke Akindele (Jenifa):
Ilumọọka oṣere
tiata miran to tun bi ibeji ni Funke Akindele, ọkọ rẹ keji, Abddulrasheed Bello
ti ọpọ eeyan mọ si JJC Skillz, lo si bi awọn ọmọ naa fun.
Osu Kejila ọdun
2018 ni Funke, ti ọpọ eeyan mọ si Jenifa, bi awọn ibeji naa, eyi to pa orukọ rẹ
da si mama ibeji.
Taiwo Aromokun:
Ibeji di
iran lo yẹ ka maa pe gbajumọ oṣere tiata, Taiwo Aromokun nitori ibeji ni, to si
tun bi ibeji ni igba meji ọtọọtọ.
Ọkùnrin meji
ni awọn ibeji akọkọ ti Taiwo kọkọ bi, oṣu keje ọdun 2013 si lo bi awọn ìbejì
naa fun ọkọ rẹ, Olayemi Abimbola, bi o tilẹ jẹ pe igbeyawo laarin tọkọtaya ọhun
ti tuka.
Orúkọ awọn
ibeji akọkọ naa ni Jade ati Jamine nigba ti Taiwo tun bi ibeji miran lọdun
2017, ọkùnrin kan ati obinrin kan si ni awọn ọmọ naa.
Muyiwa Ademola (Muyi Authentic):
Osere tiata,
Olootu ati Oludari ere ni Muyiwa Ademola, ti ọpọ eeyan mọ si Muyi Authentic, ti
iyawo rẹ, Omolara si bi ibeji fun.
Oṣu Keje ọdun
1997 ni Muyiwa bi awọn ibeji ọkùnrin meji naa,lasiko ti okiki rẹ ko tii tan
ninu isẹ tiata, ti awọn ibeji ọhun si ti pe ọdún mẹtalelogun ni ọdun 2020.
Damola Olatunji:
Damola
Olatunji ati iyawo rẹ Bukola Adeyemi, ti ọpọ eeyan mọ si Bukola Arugba, jẹ oṣere
tiata to gbajugbaja, ti aye si n fẹ wọn.
Awọn mejeeji
bi ibeji ni ọdun 2015 lẹyin ti igbeyawo akọkọ Damola fi ori sapọn ni ọdun 2014.
Ọkùnrin kan
ati obinrin kan ni awọn ibeji naa, ti wọn jẹ akọbi awọn oṣere tiata mejeeji, ti
awọn ọmọ naa ko si tii gba aburo di akoko yii.
Lati: BBC
No comments:
Post a Comment