BUHARI, TINUBU, AWỌN GOMINA, PDP BANUJẸ LORI IKU AJIMỌBI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 26, 2020

BUHARI, TINUBU, AWỌN GOMINA, PDP BANUJẸ LORI IKU AJIMỌBI


'A o pade leti odo, odo didan' l'orin ti pupọ awọn oloṣelu at'awọn ọmọ Naijiria kaakiri agbaye n kọ bayii fun Gomina ana n'ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi to jaye laye lẹni aadọrin ọdun l'ọjọ Tọside ana. 

Ajimọbi ni igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu APC, ẹkun ilẹ Yoruba, ti wọn si yan an gẹgẹ bi alaga fidihẹ f'ẹgbẹ baa nilu Abuja lẹyin ti ile-ẹjọ le Adams Ọṣhiọmhọlẹ danu. 

Aarẹ Muhammadu Buhari, awọn gomina patapata lorilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Tinubu at'awọn agbaagba ninu ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ni wọn ti kanminu lori iku Ajimọbi, ti wọn si n fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ si idile oloogbe.

Lara awọn gomina ti wọn fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ ni Gomina Ṣeyi Makinde t'ipinlẹ Ọyọ; Kayọde Fayẹmi t'ipinlẹ Ekiti; Babajide Sanwo-Olu t'ipinlẹ Eko; Dapọ Abiọdun t'ipinlẹ Ogun ati Gboyega Oyetọla t'ipinlẹ Ọṣun.

Yatọ si awọn wọnyi, ẹgbẹ oṣelu PDP naa ko gbẹyin ninu awọn to fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ síjọba ipinlẹ Ọyọ. ati orilẹ-ede Naijiria.

Ninu lẹta ibanikẹdun rẹ, Aarẹ Buhari sọ pe awọn ipa ti oloogbe naa ko l'ẹka eto idagbasoke n'ipinlẹ Ọyọ ati orilẹ-ede Najiria ni yoo maa wa n'iranti titi lai.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI